Guidance

Notice of rights and entitlements Yoruba (PACE Code C) (accessible version)

Updated 27 January 2020

Ranti awọn ẹtọ rẹ ni igba ti o wa ni atimọle

Awọn ẹtọ ti a Pese fun ọ ni yi a se onigbọwọ fun labẹ ofin ni orilẹ-ede England ati Wales ati pe a gba pẹlu Àjọ EU Directive 2012/13 lori ẹtọ rẹ si iwifun ninu ilana iwadi ti iwa buburu.

Awọn ẹtọ rẹ ni ile iṣẹ agọ ọlọpa ni a kọ si ibi

A si tun ni awọn alaye ni ẹkurẹrẹ ni ori ẹsẹ kinni (1) titidi ori ẹsẹ kọkanla (11).

Ẹkurẹrẹ alaye wa ninu Iwe Ilana Òfin ti ọlọpa C.

  1. Sọ fun ọlọpa ti o ba fẹ ki agbẹjọro kan o ran ọ lọwọ ni igba ti o ba wa ni agọ ọlọpa. Eyii jẹ ọfẹ.

  2. Sọ fun ọlọpa ti o ba ni ẹnikẹni ti o fẹ sọ ibi ti o wa fún. Eyii jẹ ọfẹ.

  3. Sọ fun ọlọpa ti o ba fẹ wo awọn ofin wọn- eyi jẹ Ilana Ofin Ise wọn.

  4. Sọ fun ọlọpa ti o ba nilo itọju ara. Sọ fun ọlọpa ti ara rẹ ko ba ya tabi ti o ba fi ara sèèse. Ọfẹ ni ile iwosan.

  5. Ti a ba bi o ni ibeere nipa awọn ẹsẹ kan ti a fura si, o ko nilo lati sọ ohunkohun. Ẹwẹ, o le se akoba fun aroye rẹ ti o ko ba dahun si ibeere ohun kan eyiti o nilo t’oba ya ni ile ẹjọ. Ohun k’ohun ti o ba sọ ni a o lo gẹgẹbi ẹri fun ọ.

  6. Ọlọpa ni lati se alaye fun ọ lori ẹsẹ ti a ro pe o da ati idi ti a fi mu ọ ti a si fi ọ si inu atimọle.

  7. Ọloọpa ni lati jẹ ki iwọ tabi agbẹjọro rẹ ri awọn iwe akọsilẹ ati ipamọ fun idi ti a fi mu ọ ti o si wa ni àtìmọ́ lé àti nipa asiko rẹ ni agọ ọlọpa.

  8. Ti o ba nilo atumọ ede, ọlọpa naa gbọdọ pese ọkan fun ọ. O le ni awọn iwe ti a tumọ pẹlu. Eyii jẹ ọfẹ.

  9. Sọ fun ọlọpa ti o kii ba se ọmọ orilẹ-ede Britain ti o si fẹ kan si ajọ tabi aṣoju orilẹ-ede rẹ abi o fẹ ki a sọ fun wọn pe o wa ninu atimọle. Eyii jẹ ọfẹ.

  10. Ọlọpa ni lati sọ iye igba ti o ma fi wa ninu atimọle fun ọ.

  11. Ti a ba fi ẹsun kan ọ ti ẹjọ rẹ si de ile ẹjọ, iwọ tabi agbẹjọro rẹ ni ẹtọ lati ri iwe ipẹjọ ki igbẹjọ to bẹrẹ.

Ti awon ẹtọ wọnyi ko ba da ọ l’oju, , sọ fun ọlọpa alamojuto naa

Wo awọn oju-iwe akojọ naa fun awọn alaye ni ẹkunrẹrẹ nipa bi ọlọpa se yẹ ki o se abojuto ati itọju rẹ.

Ẹya Akiyesi awọn Ẹtọ ati Ajẹmọnu ni ipa lati 21 August 2019 (ojo kanle logun, osu kejo odun 2019)

Jọwọ fi iwifun yi pamọ ki o si ka-a ni kiakia. Yo ran ọ lọwọ lati se awọn ipinnu nigba ti o wa ni agọ ọlọpa.

1. Gbigba agbẹjọro lati ran ọ lọwọ.

  • Agbẹjọro le ran ọ lọwọ o si le fun ọ ni imọran nipa ofin.
  • Bíbèèrè lati sọrọ pẹlu agbẹjọro ko jẹki o ri bii wipe o ti se ohun ki ko bojumu.
  • Olopa Alatimọle gbọdọ beere lọwọ rẹ bi o ba fẹ imọran agbẹjọro. Eyii jẹ ọfẹ.
  • Awọn ọlọpa gbọdọ jẹki o ba agbẹjọro sọrọ ni igbakugba, ọsan tabi asaalẹ, nigbati o bawa ni agọ ọlọpa.
  • Bi o ba beere fun imọran ofin, a ki nsaba gba ki awọn ọlọpa beere ibeere kankan lọwoọ rẹ titi ti o fi ni anfaani lati ba agbẹjoọro kan sọrọ. Nigbati awọn ọlọpa ba beere awọn ibeere lọwọ rẹ, o le beere fun agbẹjọro lati wa ninu yara pẹlu rẹ.
  • Bi o ba ti sọfun awọn ọlọpa wipe o ko fọ imọran ofin sugbon o wa yi ọkan rẹ pada, sọ fun ọlọpa alatimọle ti yoo wa ran ọ lọwọ lati kan si agbẹjọro kan.
  • Bi agbẹjọro kan ko ba yọju tabi kan si ọ ni agọ ọlọpa, tabi o nilo lati ba agbẹjọro kan sọrọ lẹẹkansi, beere lọwọ awọn ọlọpa lati kan si wọn lẹẹkansi.

Imọran ofin ọfẹ nipa awọn ohun ti ko l’ewu pupọ:

  • Ninu awon ẹjọ kọọkan ti ko l’ewu pupọ, awọn akọṣẹmọṣẹ oludamọran lati Iṣẹ Aabo Arufin (CDS) taara nikan lo le gbani n’ imọran ofin ọfẹ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ ayafi ti agbẹjọro ba wa lati agọ ọlọpa, bii:
    • Awọn ọloọpa fẹ beere awọn ibeere nipa ẹsẹ kan tabi se eto idanimo eleri.
    • o nilo iranlọwọ lati ọdọ “agbalagba ti o yẹ”. Wo “Awọn eniyan ti o nilo iranlọwọ”.
    • o kole soro lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ, tabi
    • o fi ẹsun ihuwasi odi lile kan awọn ọlọpa.

Igbati igbani n’ imọran ofin ọfẹ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ ki se fun Iṣẹ Aabo Arufin (CDS) Taara nikan:

  • O le beere lati ba agbẹjọro kan ti o mọ sọrọ o ko si nilo lati sanwo ti wọn ba se ise iranwọ agbẹjọro. Bi o ko ba mọ agbẹjọro kankan tabi a ko le kan si agbẹjọro ti o mọ, o le ba agbẹjọro ti o wa lẹnu iṣẹ sọrọ. Eyii jẹ ọfẹ.

  • Agbẹjọro ti o wa lẹnu iṣẹ koni ohunkohun se pẹlu awọn ọlọpa.

Lati s’eto fun imọran ofin ọfẹ:

  • Awọn ọlọpa yo kan si Ibi Ipe Agbẹjọro Aabo (DSCC). DSCC naa yo s’eto fun lati gba imoran ofin, lati ọdọ CDS Taara, lati ọdọ agbẹjọro kan ti o ti beere fun tabi lati ọdọ Agbẹjọro ti o wa lenu iṣẹ naa.

  • DSCC ati CDS Taara naa jẹ awọn iṣẹ ara-ẹni to nseto imoran ofin ọfẹ ti ko si ni ohunkohun se pẹlu awọn ọlọpa.

Bi o ba fẹ sanwo fun imọran ofin fun’ra rẹ:

  • Ni gbogbo igba o le san owo fun imọran ofin ti o ba fẹ bẹ.
  • Nigbati igbani n’ imọran ofin ọfẹ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ wa fun CDS Taara nikan o si tun le ba agbẹjọro ti o fẹ sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ bi o ba fẹ bẹ, sugbon iranwọ ofin ko ni san’wo fun wọwon si le ni ki o sanwo fun wọn. DSCC naa yo ba ọ kan si agbejoro rẹ.
  • O l’ẹtọ lati ba agbẹjọro ti o yan sọrọ ni kọkọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ tabi wọn le pinnu lati wa ri ọ ni agọ ọlọpa.
  • Bi agbẹjọro ti o fẹ ko ba see kan si, awọn ọlọpa si le pe DSCC naa lati s’eto imọran ofin ọfẹ lati ọdọ Agbẹjọro ti o wa lẹnu iṣẹ.

2. Sisọ fun ẹnikan wipe o wa ni agọ ọlọpa

  • O le beere pe ki awọn ọlọpa ba ọ kan si ẹnikan ti o yẹ lati mọ pe o wa ni agọ ọlọpa. Eyii jẹ ọfẹ.
  • Wọn yo ba ọ kan si ẹnikan ni kiakia.

3. Wiwo awọn Ofin Ise

  • Awon Ofin Ise jẹ awọn ofin ti yo sọ ohun ti awọn ọlọpa lese ati ohun ti wọn ko le se nigbati o ba wa ni agọ ọlọpa.
  • Awọn ọlọpa yo jẹki o ka Awon Ofin Ise naa, sugbon o ko le s’eyi ti yo ba da awọn ọlọpa duro nipa wiwadi boya o ti rufin.
  • Bi o ba fe ka Awọn Ofin Ise naa, so fun Ọlọpa Alatimọle naa

4. Gbigba iranwọ iwosan ti ara rẹ ba ya tabi ti o ba sese

  • Sọ fun awọn ọlọpa bi ara rẹ ko ba ya tabi nilo oogun tabi ti o ba sese. Wọn yo pe dokita tabi nọọsi tabi akọṣẹmọṣẹ iwosan miiran ọfeẹ si ni.
  • A le gba o laaye lati lo oogun tirẹ, sugbọn awọn ọlọpa yo kọkọ yẹwo naa. Nọọsi kan yo kọkọ ri ọ na, sugbọn awọn ọlọpa yo ransẹ pe dokita kan bi o ba nilo ọkan. O le beere lati ri dokita miiran, sugbọn o le ni lati sanwo fun eyi.

5. Ẹtọ lati wa ni idakẹ

Ti a ba beere ibeere lọwọ rẹ nipa ẹsẹ ti a fura si, o ko nilo lati sọ ohunkohun.

Ẹwẹ, o le se akoba fun aroye rẹ ti o ko ba dahun si ibeere ohun kan eyiti o nilo t’oba ya ni ile ẹjọ.

Ohun k’ohun ti o ba sọ ni a o lo gẹgẹbi ẹri fun ọ.

6. Mimọ nipa ẹsẹ ti a fura si pe o sẹ ati mimọ idi ti a fii mu o ati ti ọ mọ’le

  • Ọlọpa gbọdọ sọ nipa iru ẹsẹ ti wọn ro pe o ti da.. Eyi pẹlu igba ati ibi ti wọn ro pe o ti sẹ.
  • Ọlọpa gbọdọ sọ idi ti woọn fi ro pe o sẹ ẹsẹ naa fun ọ ati idi ti wọn fi gbagbọ pe o yẹ ki awọn mu ọ.
  • Ni agọ ọlọpa, ọlọpa naa gbọdọ sọ idi ti wọn fi gbagbọ pe o yẹ fun atimọse fun ọ.
  • Ki a to bi ọ ni ibeere kankan nipa ẹsẹ kankan, ọlọpa ni lati fun iwọ ati agbẹjọro rẹ ni iwifun ti o to nipa ohun ti ọlọpa ro pe o se ki o le ba gba ara rẹ silẹ, sugbọn kii se akoko ti yoo pa iwadi ọlọpa naa lara.
  • Eyi wa fun awọn ẹsẹ miran ti awọn ọlọpa ro pe o se.

7. Wiwo awọn iwe akọsilẹ ati ipamọ nipa mímú ati itimọle rẹ.

  • Ni igba ti o ba wa ni atimọle ni agọ ọlọpa, ọlọpa gbọdọ:
    • Akọsilẹ ninu iwe ipamọ rẹ, idi ti wọn fi mu ọ ati idi ti wọn fi gbagbọ pe o ye ki o wa ni atimọle.
    • Je ki iwọ ati agbẹjọro rẹ wo iwe akọsilẹ rẹ. Ọlọpa ahamọ yoo s’eto eyi.
  • Eyi wa fun awọn ẹsẹ miran ti olopa ro pe o sẹ.
  • Ọlọpa gbọdọ gba ki iwọ tabi agbẹjọro rẹ ni anfaani si awọn iwe ati ohun ti o yẹ lilo lati gbogun ti ofin ti o sokun fa mimu ati titi ọ mọle.

8. Gbigba atumọ ede ati itumọ awọn iwe kọọkan lati ran ọ lọwọ

  • Ti o ko ba le sọ tabi gbọ ede Gẹẹsi, awọn ọlọpa yo s’eto fun enikan ti o nsọ ede rẹ lati ran ọ lọwọ. Eyi jẹ ọfẹ.
  • Bi o ba jẹ odi tabi ni isoro lati sọrọ, awọn ọlọpa yo s’eto fun Atumọ Ede Gẹẹsi Ilu Britian lati ran ọ lọwọ. Eyi jẹ ọfẹ.
  • Ti o ko ba gbọ tabi sọ ede Gẹẹsi,, ọlọpa yo ba ọ gba atumọ ede lati sọ idi ti o fi wa ni atimọle. Eyi gbọdọ jẹ sise nigbogbo igba ti a ba se ipinnu lati fi ọ si ahamọ.
  • Lẹyin ipinnu kọọkan lati fi ọ si ahamọ ati leyin ti fi ẹsun ẹsẹ kan ọ, ọlọpa gbọdọ fun ọ ni iwe akọsilẹ idi atimọle ati ẹsun ẹsẹ rẹ ni ede rẹ, ayafi ti idi pataki lati ma se ba wa. Awọn ni:
    • Ti o ba pinu pe o ko nilo akọsilẹ naa lati fi gba ararẹ silẹ nitori pe o ni oye kikun nipa ohun ti o nsẹlẹ ati atunbọtan aini iwe akọsilẹyi ti o si ti ni anfaani lati bi agbẹjọro fun iranlọwọ ati se ipinnu. O gbọdọ f’ọwọ si nipa iwe kikọ. -T’oba jẹ nipa itumọ ede ọlọrọ tabi akojọ nipa atumọ ede dipo kikọ itumọ ede ni yoo to fun ọ lati gba ara rẹ silẹ ti o si ni oye ohun to nsẹlẹ. Ọlọpa alahamọ gbọdọ f’ọwọ si eyi.
  • Nigbati awọn ọlọpa ba beere ibeere lọwọ rẹ ti wọn ko si gba ohun silẹ, atumọ ede naa yoo ka awọn ibeere ati idahun rẹ silẹ ni ede tire. O ni anfaani lati yẹ eyi wo ki o to f’ọwọ sii gẹgẹbi akọsilẹ to yẹ.
  • Bi o ba fẹ sọ gbolohun ọrọ kan fun awọn ọlọpa, atumọ ede naa yoo se ẹda gbolohun naa ni ede tirẹ fun ọ lati yẹẹwo ki o si f’ọwọ pe o tọ.
  • O si tun l’ẹtọ si itumọ ede akiyesi yi. Ti ko ba si itumọ ede l’arọwọto, o nilo lati gba iwifun naa nipasẹ atumọ ede kan ki o si fun ọ ni itumọ ede naa lai fi akoko s’ofo.

9. Kikan si ajọ tabi aṣoju orilẹ-ede rẹ

Ti o kii ba se ọmọ orilẹ-ede Britain, o le sọ fun awọn ọlọpa wipe o fẹ kan si Ajọ Agba, Ajọ Asoju tabi Igbimọ Asoju Orilẹ-ede rẹ lati sọ ibi ti o wa fun wọn ati idi ti o fi wa ni agọ ọlọpa. Wọn tun le bẹ o wo ni ikọkọ tabi s’eto fun agbẹjọro lati ri ọ.

10. Igba wo l’ole wa ni atimọle da

  • O le wa ni atimọle fun wakati 24 lai gbe ọ lọ si’le ẹjọ. Eyi le pẹayafi ti adajọ tabi adajọ agba ni ile-ẹjọ giga ba da ẹjọ naa ti Ọga Ọlọpa tabi ile-ẹjọ si gba laaye lati sẹlẹ. Lẹyin wakati 36, ile-ẹjọ nikan l’ole gba awọn ọlọpa laaye lati ti ọ mọ’le fun akoko die si lai pe ọ l’ẹjọ.
  • Lati igba de igba ọga ọlọpa kan gbọdo ma wo ẹjọ rẹ lati ri daju pe a o da ọ duro si agọ ọlọpa. Eyi ni a npe ni atunyẹwo, ọlọpa naa si ni ọlọpa ayẹwo. Afi ti o ko ba si ni ipo ilera, o ni ẹtọ lati le sọrọ si ipinnu yi nipa kikọ iwe tabi sisọ fun ọlọpa ayẹwo tabi lori ala amuhunmaworan kan. Agbẹjọro rẹ naa ni ẹtọ si ọrọ sisọ lori eyi, dipo rẹ.
  • Ti ọlọpa ayẹwo ko ba fi ọ silẹ, a ni lati mọ b’ose jẹ ati idi to wa l’akọsilẹ ninu akọsilẹ ahamọ rẹ.
  • Ti atimọle rẹ ko ba nilo, a gbọdọ fi ọ silẹ. Ti awọn ọlọpa ba sọ fun ọ pe awọn fẹ tẹsiwaju lati se iwaadi ẹsun naa, a o fi ọ silẹ boya nipa gbigba beli tabi aigba beli. T’o ba jẹ beli, wọn gbọdọ fun ọ ni iwe afiyesi lati sọ fun ọ pe o gbọdọ pada si agọ ọlọpa ati nipa ohunkohun to ba rọ mọ beli rẹ.
  • Ti awọn ọlọpa ba fẹ beere pe ki ile-ẹjọ fi kun akoko itimọle rẹ:
    • O ni lati wa ni ile ẹjọ fun ijẹjọ ayafi ti eto ala amohunmaworan ba wa, ki o le ba ri ati gbọ awọn eniyan ninu ile ẹjọ awọn naa yoo si le ri ati gbọ ọ.
    • A o le s’eto ala amohunmaworan ayafi ti ọlọpa alabojuto sọ pe o bojumu, agbẹjọro kan ba ti gba ọ nimọran nipa ilo rẹ ati ti iwọ naa ba f’ọwọ si.
    • O gbọdọ gba ẹda iwifun naa ti o sọ fun ile-ẹjọ nipa ẹri ati idi ti ọlọpa se fẹ ko wa ni ahamọ.
    • O ni ẹtọ lati ni agbẹjọro kan pẹlu rẹ fun ijẹjọ ni ile ẹjọ.
    • A o gba ọlọpa laye lati fi ọ si ahamọ ti ile ẹjọ ba gbagbọ pe o yẹ ati wipe ki awọn ọlọpa nse iwadi ọrọ daadaa lai fi akoko s’ofo.
  • Ti awọn ọlọpa ba ni ẹri to daju lati fi ran ọ lọ si ile ẹjọ, a le pe ọ l’ẹjọ ni agọ ọlọpa tabi nipa ifiransẹ, pe ki o fi oju ba ile ẹjọ fun idajọ.

11. Anfaani si ẹri ti ọrọ rẹ ba lọ si ile ẹjọ

Ti a ba fi ẹsun ẹsẹ kan kàn ọ, iwọ tabi agbẹjọro rẹ ni lati ri ẹri ti a fi tako ọ ati ẹri ti o le ran ọ lọwọ lati gba ara rẹ silẹ.. Eyi gbọdọ waye ki igbẹjọ rẹ to bẹrẹ. Ọlọpa ati awon Ilana Ise Idajo gbọdọ s’eto eyi ki wọn si pese anfaani si awọn iwe ti o yẹ.

Awọn ohun miiran lati mọ nipa wiwa ni Agọ ọlọpa

Bi o se yẹ ki a tọju ati mojuto ọ

Awọn akọsilẹ yii sọ fun ọ nipa ohun ti o le reti nigbati a ba fi ọ si agọ ọlọpa. Lati wadi sii, beere alti ri Awon Ise Ofin. Eyi pẹlu akojọ ibi ti o ti le ri iwifun sii nipa ọkọọkan nipa awọn ohun wọnyi. Beere lọwọ ọlọpa ahamọ bi o ba ni ibeere Kankan.

Awọn eniyan ti o nilo iranlọwọ

  • Bi o ko ba ti pe omo odun mejidilogun (18) tabi ti o ni ipalara, fun apẹẹrẹ ti o ni isoro ẹkọ tabi ailera ọpọlọ, o ni ẹtọ si ẹnikan lati wa pẹlu rẹ nigbati awọn ọlọpa ba nse ohun kan. Ẹni yi ni “agba to yẹ” wọn yo si gba ẹda akiyesi yi.
  • Agba rẹ kan yoo ran ọ lọwọ lati mọ ohun to nsẹlẹ yoo si ba ọ s’amojuto awọn ipinnu rẹ. O gbọdọ wa pẹlu rẹ nigbati awọn ọlọpa ba nsọ fun ọ nipa awọn ẹọ rẹ ati idi ti a fi wa ni agọ ọlọpa. O tun gbọdọ wa pẹlu rẹ nigbati ọlọpa ba nka awọn ikilọ ọlọpa fun ọ.
  • Agba rẹ to yẹ naa le beere agbẹjọro fun ọ.
  • O le ba agbẹjọro rẹ sọrọ laisi agba rẹ to yẹ ninu yara naa bi o ba fẹ.
  • Awọn ọlọpa naa le nilo lati se ohun kan ninu awọn ohun akojọ to wa nisale yi nigbati o ba wa ni agọ olọpa. Ayafi ti awọn akanse idi ba wa, agba rẹ ti o yẹ gbọdọ wa pẹlu rẹ fun gbogbo akoko naa bi awọn ọlọpa ba se ohunkohun ninu awọn wọnyi:
    • Fi ọrọ wa ọ l’ẹnu wo tabi beere pe ki f’ọwọ si iwe kikọ tabi awọn akọsilẹ ọlọpa.
    • Bọ ju asọ ita rẹ lọ lati yẹ ọ wo.
    • Tẹka, ya aworan tabi ayẹwo idanimọ (DNA) tabi awọn ayẹwo miiran.
    • Se ohunkohun ti o niise pẹlu eto ida ẹlẹri mọ.
  • A gbọdọ fun agba rẹ ni aaye lati wa larọwọto rẹ tabi lori ẹrọ ibataẹnisọrọ lati ran ọ lọwọ, nigbati awọn ọlọpa ba nse ayẹwo ẹsun rẹ lati rii boya o ma wa ni atimọle sii.
  • Ti agba rẹ ba ri aaye, wọn gbọdo wa nibẹ nigbati ọlọpa naa ba nfi ẹsun kan ọ.

Gbigba alaye nipa akoko rẹ ni agọ ọlọpa

  • Gbogbo ohun ti o ba sẹlẹ si ọ nigbati o ba wa ni agọ ọlọpa ni a ka silẹ Eyi ni a npe ni Akasilẹ Ahamọ.

  • Nigbati o ba kuro ni agọ ọlọpa naa, iwọ, agbẹjọro rẹ tabi agba rẹ ti o yẹ le beere fun ẹda Akasilẹ Ahamọ. Awọn ọlọpa ni lati fun ọ ni ẹda Akasilẹ Ahamọ rẹ ni kopẹkopẹ.

  • O le beere lọwọ awọn ọlọpa fun ẹda Akasilẹ Ahamọ rẹ titi di osu 12 lẹyin ti o ti kuro ni agọ ọlọpa.

Biba awọn eniyan sọrọ

  • Pẹlu biba agbẹjọro sọrọ ati sisọ fun ẹnikan nipa atimọle rẹ a o ma tun gba ọ laaye lati se ipe kan.
  • Beere lọwọ awọn ọlọpa bi o ba fẹ pe.
  • O si tun le beere fun kalamu ati iwe pelebe.
  • O le ni awọn alejo sugbọn ọlọpa ahamọ le kọ lati gba iyẹn.

Ile Ẹwọn rẹ

  • Bi o ba seese o yẹ ki o da wa ninu ile ẹwọn.
  • O yẹ ki o mọ́, lọwọọrọ ati ni òye.
  • Asọ itẹ rẹ gbọdọ mọ ki o si wa ni titodaadaa.
  • A gbọdọ gba ọ laaye lati lo ile iyagbẹ ki o si wẹ.

Awon ohun ohun elo ti ara – ilera, imototo ati itoju

  • Won ni lati beere lowo re ti o ba fe ba wa soro ni ibi koko pelu okan ninu awon osise abojuto nipa ohun to jomo eto ara ti o nii se pelu ilera, imototo ati ohun elo ti o nilo tabi ti o jo mo e nigba ti o ba wa ni atimole.
  • Olopa yo se eto lati pese ohun ti a lero pe o nilo lati ba aini re pade. Ti o ba fe, eni ti o ba e soro le je eya abo tabi ako bi tire.
  • Ti o ba je obirin ti o tii pe omo odun 18 (meji dilogun) tabi ti o ju bee lo, a ni lati beere lowo re ti o ba fe tabi ti o ba ma nilo awon ohun ti fi se nkan osu ni igba ti o ba wa ni atimole ati wi pe a ni lati so fun e pe:
    • gbogbo ohun elo ni a o pese fun o ni ofe -awon ohun ipaaro wa; ati -gbogbo ohun elo yii ni awon ebi re tabi ore re le pese fun o ni apo ara won ti awon osise abojuto wa ba fara mo o.
  • Ti o ba je obirin ti ko tii pe omo odun 18 (meji dilogun), osise abojuto maa seto wi pe eni ti o je obirin wa ni ago olopa lati toju re ati pe won yo beere ti o ba fe ohun elo ti ara ati ti nkan osu

Awon asọ

Bi a ba gba awọn asọ rẹ kuro lọwọ rẹ, awọn ọlọpa gbọdọ pese asọ omiran fun ọ.

Ounjẹ ati ohun mimu

A gbọdọ fun ọ ni ounjẹ ẹmẹta (3) lojumọ pẹlu awọn ohun mimu. O si tun le mu awọn ohun mimu laarin ounje.

Eré Idaraya

Bi o ba seese o yẹ ki a gba ọ laaye nita lojoojumọ fun atẹgun.

Nigbati awọn oọlọpa ba beere ibeere lọwọ rẹ

  • Iyara naa ye ki o mọ́ , lọwọọrọ ati ni òye.
  • O ko nilo lati dide duro.
  • O yẹ ki awọn Ọlọpa naa le sọ orukọ wọn ati ipo wọn fun ọ.
  • O yẹ ki o ni isinmi ni awọn akoko ounjẹ ati isimi fun ohun mimu lẹyin wakati meji.
  • O yẹ ki a gba o laaye fun o kere ju isinmi wakati 8 ninu wakati 24 ti o fi wa ni atimọle.

Awọn ohun elo Igbagbọ

Sọ fun oọlọpa ti o ba nilo ohunkohun ti yoo ran ọ lọwọ lati se ẹsin rẹ nigbati o ba wa ni agọ ọlọpa. Wọn le pese iwe ẹsin ati awon nklan miiran , gẹgẹ bi o se fẹ.

Awọn akoko ti awọn ofin deede nyatọ

Gbigba agbẹjọro lati ran ọ lọwọ

Awọn akanse akoko kan wa ti awọn ọlọpa nilo lati yara beere awon ibeere kan lọwọ rẹ ki o to le ba agbẹjọro kan sọrọ.. Iwifun nipa awọn akanse akoko wọnyi ni a fihan ninu Awọn Ise Ofin. Eyi nsọ ohun ti awọn ọloọpa lese tabi eyi ti wọn kole se nigbati o ba wa ni agọ ọlọpa. Bi o ba fẹ ye awọn alaye naa wo, wọn wa ni ipin ọrọ 6.6 ti Ofin C ti Awon Ise Ofin naa.

Akoko akanse kan wa ti awọn ọlọpa koni jẹki o sọrọ pẹlu agbẹjọro ti o ti yan. Ti eyi ba sẹlẹ a gbọdọ gba ọ laaye lati yan agbẹjọro miiran. Bi o ba fẹ wo awọn alaye naa, wọn wa ni Afikun B ti Ofin C ti Awon Ise Ofin naa.

Sisọ fun ẹnikan wipe o wa ni agọ ọlọpa

Awon akanse akoko kan wa ti awọn ọlọpa koni gba ki o kan si ẹnikẹni. Iwifun nipa awọn akanse akoko wọnyi wa ninu Awon Ise Ofin naa.

Bi o bafe wo ekunrere alaye naa, wọn wa ni Afikun B ti Ofin C ti Awon Ise Ofin naa.

Awọn ẹsẹ ọti mimu ati ogun oloro mimu l’akoko iwakọ

Bi o ba wa l’agọ ọlọpa nitori awọn ẹsẹ ọti mimu ati ogun oloro mimu l’akoko iwakọ, o ni ẹtọ lati ba agbẹjọro sọrọ. Ẹtọ naa koni wipe o le kọ lati fun awọn ọlọpa ni eemi rẹ, ẹjẹ tabi itọ koda ti o ko ba tii ba agbẹjọro naa sọrọ.

Idani duro labe Ofin Ilera ti Iye 1983

Awọn ọlọpa naa tun le da ọ duro ni agọ ọlọpa fun ayẹwo labẹ Ofin Ilera Ọpọlọ ti o ko bati pe ọmọ ọdun mejidinlogun tabi ju bẹ lọ atipe nitori ewu pe ihuwasi rẹ o fa ijamba lile abi iku fun ọ tabi fun ẹlomiran, o ko lero pe ki a da ọ gunlẹ si ibo miran. Bi a bati da ọ duro labẹ Ofin Ilera Ọpọlọ eyi ko tumọ si wipe a ti mu ọ fun ẹsẹ kankan.

Eyi tumọ si wipe awọn ọlọpa gbọdọ s’eto fun ọ lati ri dokita ati Akọṣẹmọṣẹ Ilera Ọpọlọ ti a fun l’asẹ lati se ayẹwo naa. A gbọdọ yẹ o wo laarin wakati 24 ti o de agọ ọlọpa, tabi ti a ti da ọ duro si agọ ọlọpa, sugbọn awọn ọlọpa yọ gbiyanju lati s’eto yi ni kiakia. Ni agọ ọlọpa, akoko idaduro oni wakati 24 fun ayẹwo le lọgun fun wakati 12 si ti dokita ba ro pe o yẹ ti ọga ọlọpa naa si fọwọ si. Ni akoko yii, awọn ọlọpa le gbe ọ lo si ibi ti o yẹ kan lati jẹ ki ayẹwo naa seese.

Nigbati o ba nduro fun ayẹwo, awọn ọlọpa le s’eto fun ọ lati ri Onisẹ Ilera ti a fun ni asẹ. Wọn kole se ayẹwo naa, sugbọn wọn yo ran ọ lọwọ pẹlu awọn ailera miiran ti o le ni ati ran ọ lọwọ lati s’alaye ohun ti idanwo naa tumo si.

Awọn Alejo Ahamọ Olominira

Awọn ara ilu kan wa ti a ngba laaye lati wọle si agọ ọlọpa lai sọtẹlẹ. A npe wọn ni alejo ahamọ olominira ti wọn si nsiṣẹ naa l’atinuwa lati ri pe a ntọju awọn ti timọle daadaa ati lati le ni ẹtọ wọn.

O ko ni ẹtọ lati ri awọn alejo ahamọ olominira tabi beere pe ki wọ o bẹ ọ wo sugbọn alejọ kan le beere lati ri ọ. Bi alejo ahamọ olominira ba wa ki ọ nigbati o wa ni ahamọ wọn yo ma sisẹ l’ominira ara wọn lati ri pe aabo wa fun itọju ati ẹtọ rẹ.

Ẹwẹ, o ko nilo lati ba wọn sọrọ bi o ko ba fẹ.

Bi o ti le se ifisun

Bi o ba fẹ se ẹsun nipa bi a se ntọju rẹ, beere lati ba ọlọpa kan ti o jẹ oluyẹwo tabi ọga sọrọ. Lẹyin ti a ti fi ọ silẹ, o tun le ifisun ni agọ ọlọpa yoowu, si Ọfiisi Ajọ fun Ihuwasi Ọlọpa (IOPC) tabi nipasẹ agbẹjọro kan tabi MP to nduro fun ọ.